DODOnDAWA Lyrics By Testimony Jaga

Talo da?
Nibo lo ti wa?
God that created the heaven and the earth
Who was there when He was created?
Ọba to da aye atọrun ẹ jọ nibo lo n gbe?
Ta lo mọ address rẹ?
Can somebody answer me, eh yah, eh yah
Dodondawa
Dodondawa
Ehn ehn o ya
Dodondawa
Ọba to fọrọ daye tẹnikan o fọrọ da (Dodondawa)
Opo to saye ro tẹnikan o gbe ro (Dodondawa)
Ọba ta gbara to gbara le ẹnikankan (Dodondawa)
Ọba ti gbogbo aye n bọ ti o bọ ẹnikankan sẹ (Dodondawa)
Ọba ti gbogbo aye pe to o pe ẹnikankan (Dodondawa)
Ọba ta sa tọ lọ to o sa tọ ẹnikankan ni (Dodondawa)
O dara rẹ, o yanra ẹ, o fara ẹ j'ọba ni (Dodondawa)
Ọba ti n gbadubalẹ awọn lọbalọba (Dodondawa)
Ọba to ti n jọba kọba aye kan to ma jọba (Dodondawa)
Be pe l'Ọba Ọba ni n jẹ Ọba afẹru jọba ni (Dodondawa)
Bẹ dẹ pe l'Ọba Ọba ni jẹ, Ọba awọn ọba ni (Dodondawa)
Iwaju lo kọ sibi kan wọn a ni good morning (Dodondawa)
Osi lo kọ sibi kan wọn a ni good afternoon (Dodondawa)
Ọtun lo kọ sibi kan wọn a ni good evẹning (Dodondawa)
Ẹyin lo kọ sibi kan wọn a ni good night (Dodondawa)
Ọba to da ohun gbogbo to jọba lori ohun gbogbo
Dodondawa Ọlọrun ni Dodondawa
Dodondawa ni
Dondonwa ẹda kan o le dawa
Dodondawa Ọlọrun ni Dodondawa
Ọba to ti wa kaye to ma wa ni Dodondawa oh
Titobi ni Yin Eledumare Ọlọrun awọn ọmọ ogun (Dodondawa)
Gbigbega ni Ọ Iwọ ga ju awọn oke lọ (Dodondawa)
Iwọ lo laye ati gbogbo eeyan to n pe rẹ lalaye (Dodondawa)
Boya ki n beere ta lo to ninu awọn imulẹ sẹ (Dodondawa)
Ta lo to ninu awọn ajẹ, ta lo to ninu awọn ogboni (Dodondawa)
Iran nla niyin Eledumare ṣugbọn ẹ o ṣe duro wo (Dodondawa)
Nibo lati ṣe naming rẹ, hospital wo l'ọn bi ẹ si na? (Dodondawa)
Ọlọrun ni Dodondawa, abi mo purọ? (Dodondawa)
Ipa yin bori gbogbo ipa Ọlọrun awọn ọmọ ogun (Dodondawa)
Ọba to da iku tiku o ni le pa ọkọ mi (Dodondawa)
A lẹ gbọn kọja ọgbọn, ẹ riran ju iran lọ, ẹ loye joye lọ (Dodondawa)
Ẹ n dari aye ati ọrun lẹẹkan ṣoṣo ko dẹ rẹ yin ri (Dodondawa)
Ninu ọba aye Emorijah ko ma si iru rẹ (Dodondawa)
Awọn agbagba mẹrinlelogun wọn n kọrin yi itẹ rẹ ka ninu ọrun (Dodondawa)
Wọn kun fun iyẹ mẹfa mẹfa, wọn fi meji boju wọn (Dodondawa)
Wọn fi meji bo ẹsẹ wọn, wọn wa n fi iyẹ meji to ku fo
Dodondawa Ọlọrun ni Dodondawa
Dodondawa ni
Dondonwa ẹda kan o le dawa
Dodondawa Ọlọrun ni dodondawa
Ọba to ti wa kaye to ma wa ni Dodondawa oh
Dodondawa Ọlọrun ni Dodondawa
Dodondawa ni
Dondonwa ẹda kan o le dawa
Dodondawa Ọlọrun ni dodondawa
Ọba to ti wa kaye to ma wa ni Dodondawa oh