Ààrẹ Lyrics By Brymo

Eré òkúta àti gíláàsì
Mo ṣáná si, ó máa ta pàòpàò
Ọlọpá wá o, ó máa gba rìbá
Òrékelẹwà jẹ a ṣeré
Eré òkúta àti gíláàsì
Mo ṣáná si, ó máa ta pàòpàò
Ọlọpá wá o, ó máa gba rìbá
Òrékelẹwà, jẹ a ṣeré
Eré òkúta àti gíláàsì
Mo ṣáná si, ó máa ta pàòpàò
Ẹku owurọ o
Ìròyìn láti ìgboro la mú wá kàn yín létí
Wọn ní, “Ní òwúrọ yìí, àwọn ọmọ éèèsi!
Wọn ti jà wọgboro
Wọn dẹ ti ń dáná sunlé
Wọn tun dáná soko
Àtọkọ ayọkẹlẹ àti èyí tí ò yọkẹlẹ
Gbogbo ẹ l’ọn dáná sun”
Ẹ gbélé yín o
Ẹ ṣọra yín o
Ẹ pe àwọn ọmọ yín sọdọ
Èyí tí ò bá lọ sílé ìwé, kó jókòó
Kí Ọlọrun kí ó máa ṣọ gbogbo wa o
Láyọ o, ẹ ṣe
Ààrẹ ń bọ lájò
Àwọn ọmọwé takùn sọrùn láàfin
Àwọn ọjẹlú dúró ṣigidi ọkọ òfurufú
Èmi bàbá ọba, mo dúró ṣigidi, orí mi ló gbé mi kore
Ààrẹ ń bọ lájò
Àwọn ọmọwé takùn sọrùn láàfin
Àwọn ọjẹlú dúró ṣigidi ọkọ òfurufú
Èmi bàbá ọba, mo dúró ṣigidi, orí mi ló gbé mi k’ore